Oyo State
Orikis from around Oyo State, South West Nigeria
Omo Akano gudugbalogun
Omo Olode Okuta
Omo Abe sho bi esho ogun
Afi owo si inu asho ofi fun obinrin sha
Agbe na wo ju aya re loganjo our
O wo Sokoto kembe re bi ija
Won le e leyin, on le awa iwa ju
Omo oke tolu, oko ilu bantata loke odo
Omo labire
Omo oshogun shogun shemunimuni
Omo obalufon Shekutu iwo
Omo ekun fin tori tori
Omo ekun fin tiru tiru
Omo ekun tagbiri gbere nija
Omo osan pon gorin gorin
Omo ki enikeni ma rin bi baba mi
Omo ajin jin dun du du, ki enikeni ma rin babami
Omo oshogun shogun, marugbole inu-igbe jogun ilaya
Omo okan niwo gbongbontu
Omo arun guduru wo ile ede, mo bi timi ninu
Omo apakuta run perere
Omo ajaguna
Omo kan ni iwo gangan
Omo olunlade
Omo egun lolemi lona oko
Omo oosa lolemi lona odo
Omo niwonwo omo saadi
Omo aboko boko bejire
Omo ada sho ti ole o le gbe
Omo obi tiaye Obi edun
Omo Agbonrin Baba Ibiduni
Omo abosha oko no ni rawa
Niresa o! Niresa! Omomode Niresa ile!